This is the official blog site of Land of God Evangelical Drama and Film Ministries (LOGEMmin.) based in Ogun State, Nigeria. Motto: Acting the Word in God's Land by Faith Contact us @ 07038568584, 08063044454. top4ever01@gmail.com

Thursday, 10 March 2022

ÀJÒ ÀRÈMABỌ̀

 


Ẹwí fún Lámọrín kódúró n'lé,

Ẹsọ fún Tàmẹ̀dù pé kó fìdí m'ágbàlá baba tó bíi lọ́mọ...


Ẹṣí i létí kóle rántí,

Ẹnà á ní pàṣán ọ̀rọ̀ ní yàrá,

Ẹgbà á n'ímọ̀ràn lọ́ọ̀dẹ̀,

Ẹjẹ́ kó mọ'rú ọṣẹ́ táyé fií ṣ'elétí ikún ọmọ,


Ẹjẹ́ kó mọ'rú ìyà tíí j'aláìgbẹ̀kọ́ bíi ti Dínà ọmọ Jákọ́bù,

Ẹni wọ́n wí fún pé kó dúró n'lé

Ẹni wọ́n kì nílọ̀ pé kó f'ìdí m'ágbàlá,

Kàkà kí Dínà tẹ́tí gbọ́'hun baba rẹ nwí,

Kàkà kó f'ìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀lé m'ọ̀ràn òbí, 

níṣe lọ̀rẹ́ wa fò fẹ̀rẹ̀, 

t'ófẹ́ lọ f'ójú lónjẹ,


Dínà kúrò n'lé,

Ó fẹ́ lọ w'ohun ayé nṣe,

Dínà tàpá símọ̀ràn òbí,

Óṣ'ohun tí gbogbo ọmọ elétídídi nṣe,


Ó s'àpò ìyà kọ́,

Órìn'rìn àjò àrè-f'arak'ááṣá ọdẹ ayé,

Ó lọ ní kíkún, ó padà l'ófìfo!

Ó lọ l'ódindi, 

ó padà pẹ̀lú ayé àlàpà,

Ó lọ pẹ̀lú ẹ̀wú ẹ̀yẹ,

Ó padà s'ílé n'íhòhò!


Ṣékémù f'ipá gb'aṣọ ògo ìbí tí Dínà dàbo'ra!

Ah! Ìtìjú àt'ẹ̀sín dé!

Ọjà ogo Dínà di kòròfo!


Ẹbáwa já'wé gbélé jẹ́ fún gbogbo màjèsín,

Ẹf'òrí f'ìdí m'ọ́ọ̀dẹ̀ wọ́ra fún gbogbo ọ̀dọ́ ìwòyí,

Ẹní kíwọ́n yé sunlé oníle kiri


Ẹní kíwọ́n fìtẹ́lọ́rùn ṣ'ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, 

kíwọ́n f'ìwà bí Ọlọ́run ṣaṣọ àmúròde,


Ẹwí fúnwọn 'pe

gbogbo ohun t'ón dán kọ́ ni wúrà

Ẹsín wọn ní gbẹ́rẹ́ ìpàkọ́ kí wọ́n le mọ̀ 'pe; ikú nbẹ nínú ọ̀pọ̀ ìkòkò tó ṣojú rekete lóde!


Ẹní kíwọ́n yé f'ira wọn w'ówó kiri,

Ẹni kíwọ́n dúró d'àsìkò t'Ólùgbàlà ti pèsè sílẹ̀ láti d'aṣọ ògo bò wọ́n,

Ẹní kíwọ́n dúró nlé bí ti Rèbékà ọmọ Betueli,

Akínkanjú ọmọ tín fetí s'óhun òbí bá sọ,

Ó gbá'jú mọ́'ṣẹ́ baba,

Of'ìrẹ̀lẹ̀ tẹ́tí s'ímọ̀ràn òbí,

Kò rìn'rìn àrèmabọ̀, 

Bẹ́ẹ̀ni kò kó sí pánpẹ́ ibi ayé dẹ fún gbogbo ọmọ elétídídi, 

Kò sọ òbí s'írònú

Kò sọ ẹbí l'órúkọ ibi


Ẹ̀bẹ̀ mi rèé sí gbogbo òbí t'ófẹ́ f'ẹ̀yìntì j'oúnjẹ́ ọmọ, 

Ẹwí fún gbogbo ọ̀dọ́bìnrin pé; Kiwọ́n dúró n'lé, 


Lórúkọ Jésù, ọmọ wa òní rìn'rìn àjò àrèmabọ̀, Àmín.🙏

#tolulopeadeoye#

No comments:

Post a Comment

What’s your view, kindly share with us