IFE WÁ TI GBẸ
Ife wá ti gbẹ Olúwa Ọlọ́run ìgbàlà wa...🍷
Ati ṣáko jìnnà kúrò nínú ìfẹ́ Rẹ, bẹ́ẹ̀ laòsì fura...🤦♀
Ìgbónà ọkàn fún iṣẹ́ ìjèrè ọkàn ti di ohun ìgbàgbé, ọ̀pọ̀ nínu wa sítì sùn lọ l'ójú ogun...😭
Ati sọ ohun iyebíye t'Ofún wa nù nítorí àti lówó lọ́wọ́...😭
Asọ ẹ̀bùn ìgbàlà nù nìtorí àti jéèyàn lórí èèpẹ̀...😭
Ati gbàgbé wípé ohun t'Ó torí sọwá dọmọ ni kí gbogbo ayé óle fẹ́ Ọ,
Aò rántí ìlérí ìpèsè ọ̀fẹ́ tí O ṣe fún wa...😢🤦♀
Tawájí Olúwa!!!
Ati fi ọ̀rọ̀ ìjèrè ọkàn tàfàlà, àfi kí O dákun gbàwá...😭🙏🙏🙏
Òùngbẹ Rẹ ngbẹ ọkàn wa Olúwa...
àní, òùngbẹ ìwọ Ọlọ́run alààyè.😭
Ati sọ gèlè nù,🙆♀️
fìlà lohun táa nawọ́ mú,
Ati ju fìlà sílẹ́, gèlè làńgbé kiri...
Baba àfi kO gbàwá!😭
Ife wá ti gbẹ, Olúwa wá kúnwa...🙏
Ìf'àmìòróróyàn titun l'a bèèrè,
Ẹ̀yí tí kò l'ábùlà, bíi ti ọjọ́ Pẹ́ntíkọ́stì,
Baba dákun tu léwa l'órí...🔥🔥🔥
Bí ọkàn àgbọ̀nrín tií máa fà sí odò tí omi rẹ̀ tutù,
bẹ́ẹ̀ ni ọkàn wa ń fà sí Ọ, Ọlọrun.😭
Wá tún wa ṣe, kí O sọwá di tìRẹ l'akọ̀tun...
Afẹ́ padà sínú ìfẹ̀ àkọ́kọ́ nínu Rẹ🙏
Afẹ́ kí O dá iná ìyè Rẹ padà s'órí pẹpẹ àdúrà wa...
Afẹ́ kí O fún wa ni okun àti oore ọ̀fẹ́ láti gbààwẹ̀ àti láti gbàdúrà láìsinmi àti láì ṣàárẹ̀ nígbàgbogbo...
Afẹ́ máa ṣe àṣàrò nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ nígbàgbogbo🙏
Tan Ìmọ́lẹ́ Rẹ kí O sì lé òkùnkùn lọ kúrò,
Ṣí wa lójú Jẹ́kí arí Ọ Olúwa,
Fi Omi ìyè Rẹ fún gbogbo ọkàn àwa tí òùngbẹ Rẹ ńgbẹ...🙏
Ṣí etí ìgbọ́ràn wa, kí ale gbọ́ ẹ̀kọ́ tí Oń kọ́ wa...
Fún wa létí ìgbọ́ràn àti àyà tí óngba Ọ̀rọ̀ Rẹ dúró...
Jẹ́kí gbogbo ayé mọ̀ wípé Ìwọ nìkan ni Olúwa láyé àti lọ́run àti wípé tìRẹ làwa nṣe...
Èyí l'ẹ̀bẹ̀ wa, Oluwa l'Órúkọ Jésù Kristi, Àmín.🙏🙏🙏
Kàn sí👇
http://landofgodministry.blogspot.com
Fún àwọn àtẹ̀jáde wa míràn.
Jésù ni Olúwa, Àmín.🙏
#tolulopeadeoye#
No comments:
Post a Comment
What’s your view, kindly share with us